Bethel Xafe Autism Foundation

Understanding Autism

JÍJẸ́ ÈNÌYÀN Ọ̀TỌ̀ NÍ ÀWÙJỌ

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilẹ̀ Adúláwọ̀, ọ̀rọ̀ àwọn àkàndá ẹ̀dá (autism) ò kí ń yé wa, tí àwọn ìdílé tó ní àwọn ọmọ àkàndá ẹ̀dá yìí sì máa ń dojú kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro. Àwọn kan gbàgbọ́ pé àwọn tí wọ́n bí àkàndá ẹ̀dá (autism) lọ́mọ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ kan sẹ́yìn tí wọ́n wá ń jìyà rẹ̀ báyìí, nígbà tí àwọn kan lérò pé àìsàn kan tí òògùn ìbílẹ̀ tàbí àdúrà gbígbà le wò sàn ni. Ṣùgbọ́n, ó ṣe ni láàánú pé àwọn èrò yìí ló ń yọrí sí kí á máa dá àwọn tó ní autism lẹ́jọ́ tàbí kí á fi wọ́n sílẹ̀ láwọn nìkan, èyí tí kò jẹ́ kí àwọn àkàndá ẹ̀dá rí ìfẹ́, àtìlẹ́yìn àti ìtẹ́wọ́gbà tí wọ́n nílò láti gòkè àgbà láwùjọ. Síbẹ̀síbẹ̀ àròsọ lásán tí ó le yípadà tí àwọn ènìyàn bá mọ ohun tí àkàndá ẹ̀dá (autism) jẹ́ ni gbogbo àwọn èrò yìí.

Àkàndá ẹ̀dá (autism) túmọ̀ sí ipò ìdàgbàsókè tí  ó nípa lórí bí ènìyàn ṣe ń sọ̀rọ̀, bá àwọn ènìyàn ṣeré àti bí ó ṣe ń rí ìrírí ayé .  Ọpọlọ àwọn tó ní autism ní ìlànà tó ń gbà ṣe àlàyé ohun tí wọ́n bá gbọ́ yàtọ̀ sí àwọn tí kò ní . Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n le ní okun tó yàtọ̀, bíi kí wọ́n yẹ nǹkan wò fínnífínní, ọpọlọ pípé, tàbí agbára láti wonkoko mọ́ ohunkóhun tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ sí. Síbẹ̀ síbẹ̀, wọ́n le má le darapọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ ènìyàn, wọ́n le má le ṣàlàyé ara wọn bí ó ti tọ́ àti bí ó ṣe yẹ, àbí kí ìrẹ̀wẹ̀sì ó bá wọn níbi tí ìjà àbí ariwo bá pọ̀ sí. Autism ò túmọ̀ sí pé èèyàn ń ṣàìsàn tàbí pé ó ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ kan. Rárá! Ó kàn jẹ́ ọ̀nà ọ̀tọ̀ tí ènìyàn ń gbà gbé ilé-ayé, bíi kí ènìyàn máa sọ èdè mìíràn, tàbí rí ayé ní ọ̀nà tí ó yàtò . 

Láti dẹ́kun ìwà àbùkù yìí, ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé àwọn tó ní autism ò kí ń ṣe ẹ̀yà àwọn ènìyàn ‘‘tí kò pé’’ tàbí tó ‘‘lábàwọ́n’’ sí àwọn tí kò ní. Wọ́n ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ronú, sọ̀rọ̀, bá ènìyàn ṣeré, èyí tí ó dára tí ó sì dùn-ún wò gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn ènìyàn tó kù. Gbígba èyí láàyè túmọ̀ sí pé a mọ̀ pé autism ò kí ń ṣe ohun tí à ń wá ojútùú sí ṣùgbọ́n ohun tí ó yẹ ká ní òye rẹ̀ kí á sì ní kóríyá fún. Gẹ́gẹ́ bí a ti gba onírúurú àṣà, èdè, ọnà láàyè, a lè gba onírúurú ọ̀nà tí àwọn ènìyàn ń gbà ronú, ṣeré àti tí wọ́n ń gbà rí nǹkan láàyè. Autism ò kí ń ṣe ìjìyà ṣùgbọ́n ọ̀nà ọ̀tọ̀ tí ènìyàn le gbà wà láyé. Àwọn tí ó ní autism ń bùkún àwùjọ wa nípa rírí nǹkan ní ọ̀nà tó yàtọ̀, pípe àwọn èrò wa níjà, wọ́n sì ń kọ́ wa ní bí a tií ní òye àti ìmọ̀lára. Nípa gbígbárùkù ti àwọn àkàndá ẹ̀dá (autism), à ń kọ́ àwùjọ tí gbogbo ènìyàn ti le lẹ́nu ọ̀rọ̀ tí wọ́n sì le rí àpọ́nlé fún irú ènìyàn tí wọ́n jẹ́.

“Autism ò túmọ̀ sí pé èèyàn ń ṣàìsàn tàbí pé ó ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ kan. Rárá! Ó kàn jẹ́ ọ̀nà ọ̀tọ̀ tí ènìyàn ń gbà gbé ilé-ayé, bíi kí ènìyàn máa sọ èdè mìíràn, tàbí rí ayé ní ọ̀nà tí ó yàtò”

Dr. Oluwatosin Akande

Founder / CEO Bethel Xafe Autism Foundation

ÌFẸ́: ÀJÀGÀ ÀBÍ ÌRỌ̀RÙN

Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn èròjà tó lágbára tí a nílò láti fi gbárùkù ti àwọn tó ní autism. Ìfẹ́ a máa gba nǹkan mọ́ra, a máa ní òye àti sùúrù, eléyìí tí ó ṣe pàtàkì láti ṣẹ̀dá àwùjọ tí àwọn tó ní autism ó ti rí àpọ́nlé, tí wọn ó sì ní ìmọ̀lára pé wọ́n ń ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn. Kàkà tí a ó fi máa wo autism gẹ́gẹ́ bíi ìṣòro tí à ń wá ojútùú sí, ìfẹ́ á mú wa rí ẹni náà kọjá ohunkóhun tí wọ́n bá sọ pé ó ń ṣe é, a ó lè mọ rírì irú ẹni tí wọ́n jẹ́ tí a ó sì gbárùkù ti ọ̀nà ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń gbà ní ìrírí ayé. Nígbà tí àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́, àti àwùjọ bá fi ìfẹ́ hàn, wọ́n ń ṣẹ̀dá ààyè tó rọrùn fún àwọn tó ní autism láti dàgbà, kẹ́kọ̀ọ́, kí wọn ó sì dé ibi-a-fẹ́-dé wọn láyé láì sí ìbẹ̀rù ìkọ̀sílẹ̀ tàbí ti ìdájọ́. Gbígbé ilé-ayé máa ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn fún àwọn àkàndá-ẹ̀dá (autism) ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, torí ó ṣe é ṣe kí ohun tí wọ́n á kó sí ọpọlọ, ohun tó ń lọ láwùjọ àti bíbá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nira fún wọn. Ṣùgbọ́n tí a bá fi ìfẹ́ bá wọn lò pẹ̀lú ìpèníjà wọn yìí, a ó wá ọ̀nà láti faradàá fún wọn àti láti bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tí yóò gbà yé wọn. Ìfẹ́ ó fún wa ní ìwúrí láti ní òye ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan fẹ́ àti ọ̀nà tí a lè gbà ṣe àtìlẹ́yìn fún wọn. Bọ́yá nípa kíkọ́ ọ̀nà tí ó rọrùn fún wọn láti bá ènìyàn sọ̀rọ̀, ṣíṣàjọyọ̀ agbára wọn tàbí, fífi agbègbè kan kọ́ra láti jẹ́ kí wàhálà dínkù fún wọn. Ìfẹ́ á ràn wá lọ́wọ́ láti rí nǹkan gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń ríi, kí á sì ṣẹ́dá àwùjọ tí ó ń ṣe àtìlẹ́yìn tí ó sì ń kónimọ́ra.

Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìfẹ́ a máa ní ìfàyàrán, kìí ṣe fún àwọn tó ní autism nìkan ṣùgbọ́n fún àwọn ẹbí wọn àti àwọn olùtọ́jú wọn pẹ̀lú. Títọ́jú ọmọ tó ní autism tàbí gbígbárùkù ti ọ̀rẹ́ tí ó ní le wá pẹ̀lú ìpèníjà tirẹ̀ tó yàtọ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ló le mú kó ṣe é ṣe láti dojúkọ ọ́ pẹ̀lú ẹ̀mí rere àti ìrètí. Ìfẹ́ a máa ru àwọn ìdílé àti olùtọ́jú sókè láti wá àwọn ohun àmúlò tí ó le jẹ́ kí wọ́n ní ìmọ̀ sí i nípa autism, kí wọ́n sì le jà fún ẹ̀tọ́ bí àwọn olólùfẹ́ wọn ṣe le lẹ́nu ọ̀rọ̀ láwùjọ. Irú àtìlẹyìn yìí le ṣe kóríyá fún àwọn tó ní autism kí ó sì fún wọn ní ìgboyà láti lépa ohun tí ó wù wọ́n lọ́kàn, kí wọ́n darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn, kí wọ́n sì le dá sí ètò ìdàgbàsókè agbègbè wọn. Ní ilé-ẹ̀kọ́, ibi-iṣẹ́ àti agbègbè, tí a bá fi ìfẹ́ mọ̀ síi nípa autism, yóò jẹ́ kí ìmọ̀ ó pọ̀ síi, yóò sì dín àbùkù kù. Tí a bá fi ojú ìfẹ́ wo autism, a á le sún kúrò nínú ojú tí a fi ń wòó àti ìdájọ́ tí à ń ṣe fún-un, kàkà bẹ́ẹ̀ a ó máa wá ọ̀nà láti mú kí oníkálùkù dàgbàsókè àti ọ̀nà láti ṣàjọyọ̀ irú ènìyàn tí oníkálùkù jẹ́. Àwọn ìwà bíi fífetí sí ìrírí ẹni tó ní autism, bíbọ̀wọ̀ fún ààlà wọn, àbí kíkẹ́kọ̀ọ́ síi nípa ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, le fa ìyàtọ̀ tó lágbára. Ní parí parí ẹ̀, ìfẹ́ a máa bi ìdènà lulẹ̀, tí yóò sì ṣẹ̀dá àwùjọ tó kónimọ́ra.

ÀWỌN ÀṢÌṢE MẸ́FÀ TÍ A MÁA Ń ṢE

Gbígbìyànjú láti wá ojútùú sí autism

Ọ̀kan lára àwọn àṣìṣe ńlá tí a máa ń ṣe nígbà tí a bá ń ṣàkoso autism ni ṣíṣètọ́jú rẹ̀ bíi nǹkan tí ó nílò ‘‘ojútùú’’. Autism jẹ́ nǹkan tó níí ṣe pẹ̀lú ọpọlọ, èyí tó túmọ̀ sí pé ọpọlọ ẹni tó ní autism máa ń ṣiṣẹ́ yàtọ̀ sí ọpọlọ ẹni tí kò ní. Àfojúsùn wa kọ́ ni láti wo ẹni tó ní autism sàn bíkòṣe láti gbárùkù tì wọ́n kí ọgbọ́n inú wọn le dàgbà sókè kí wọ́n sì lè dé ibi tí wọ́n fẹ́ dé láyé.

Fífojú fo àwọn Ìmọ̀lára

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ní autism ni wọ́n ní òye tó ga nípa rírí, gbígbọ́, ìfọwọ́kàn àti òórùn, èyí tó le mú kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn kí ó sì má rọrùn fún wọn ní àwọn agbègbè kan. Àìkọbiara sí àwọn ìmọ̀lára yìí le yọrí sí wàhálà, ìpayà àti dídẹnukọlẹ̀. Pípèsè àwọn ohun-èlò tó ń dín ariwo kù tí wọ́n le gbé bọ etí, ohun-èlò tó le dín iná kù, àbí pípèsè ibi tí kò sí ariwo le mú ìrọ̀rùn bá wọn kó sì dín ohun tí yóò máa wọ ọpọlọ wọn kù, èyí tí yóò mú kí agbègbè náà ṣe é gbé fún wọn.

Fífojú fo Ìyàtọ̀ nínú Ìbánisọ̀rọ̀

Ìyàtọ̀ nínú bí a ṣe ń bára ẹni sọ̀rọ̀ jẹ́ ọkàn pàtàkì fún àwọn tó ní autism. Àwọn mìíràn nínú wọn le má le sọ̀rọ̀ rárá tàbí kó jẹ́ pé ọ̀nà tí wọ́n  ń gbà sọ̀rọ̀ yàtọ̀ sí ti àwọn tí kò ní . Fífi dandan lé e pé wọ́n gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ jáde láti ẹnu láì gbà wọ́n láàyè láti lo àwọn nǹkan mìíràn bíi kí wọ́n  ṣe àmì, kí wọ́n kọ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ sílẹ̀, àbí kí wọ́n lo ọ̀nà ìmọ̀-ẹ̀rọ le fa ìpinlẹ́mìí tí kò pọn dandan.

Lílo Ìjìyà Dípò Ìgbọ́ra-ẹni-yé

A lè fẹ́ sáré wagbo-dẹ́kun fún àwọn ìwà ìdánidúró mìíràn tí wọ́n bá ń hù, ṣùgbọ́n fún àwọn tó ní autism, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà tí wọ́n ń hù ló jẹ jáde láti ara àì rí ohun tí wọ́n  fẹ́ àbí kó jẹ́ pé ohun tó ń bẹ nínú ọpọlọ wọn ti pọ̀ ju ohun tó yẹ kó wà níbẹ̀ lọ. Kàkà kí á fi ìyà jẹ wọ́n, ẹ ní ìmọ̀ ohun tí ó fa ìwà náà, bóyá ìnira ni, ìpinlẹ́mìí àbí wọ́n fẹ́ sọ nǹkan kan, eléyìí yóò sì mú kí ìṣàkóso tí  ó péye wà. Ṣíṣàgbékalẹ̀ àwọn ète láti faramọ́ ìwà wọn, fífààyè gbà wọ́n láti ṣọ̀rọ̀ lọ́nà tó bá wù wọ́n àti ṣíṣàgbékalẹ̀ ọ̀nà àti mú ara wọn balẹ̀ nígbà gbogbo le mú kí àdínkù dé bá àwọn ìwà ìdínilọ́wọ́ tí wọ́n le fẹ́ hù.

Gbígbọ́kànlé Àgbékalẹ̀ àti Ìlànà-iṣẹ́ Púpọ̀ jù

Níwọ̀n bí àgbékalẹ̀ àti ìlànà-iṣẹ́ ṣe le mú ìrọ̀rùn bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ní autism, gbígbọ́ kàn lé wọn púpọ̀ jù le fa kí wọ́n má ṣe é yí padà. Èyí tí yóò jẹ́ kó nira fún wọn láti le fi ipò tuntun kọ́ra. Kíkọ wọn láti le ṣe nǹkan ní oríṣiríṣi ọ̀nà, nípa ṣíṣe àtìlẹyìn fún wọn ni ọ̀nà tí kò léwu le ràn wọ́n lọ́wọ́ láti le ní ìfàyàrán kí wọ́n sì farada àyípadà. Sísọ̀tún-sòsì láì ba ibìkan jẹ́ láàrin ìlànà-iṣẹ́ àti ṣíṣe àyípadà  jẹ́ ọ̀nà kan gbòógì tí wọ́n le gbà fi nǹkan kọra kí wọ́n sì le dá dúró.

Fífojúkéré ohun tí wọ́n le ṣe

Àṣìṣe mìíràn tí a máa ń ṣe ni fífojúkéré ohun tí àwọn tó ní autism le ṣe. Ó ṣe kókó fún wa láti mọ̀ pé àwọn tó ní autism náà ní ẹ̀bùn tó yàtọ̀, ìmọ̀ọ́ṣe àti ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù. Kí á máa ní èrò pé, ẹnìkan ò lè ṣe àwọn ohun kan nítorí pé ó ní autism le dín àǹfààní àti ìdàgbàsókè wọn kù. Gbígbà wọ́n níyànjú, láì wo ohun tí àwọn ènìyàn máa sọ, láti gbìyànjú ohun tuntun, ní ìdàgbàsókè, ṣàlàyé ara wọn, le ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ohun tí wón ò mọ̀ pé àwọn le ṣe.

ÌRÍRAN ÀTI ÌGBỌ́RÀN: Ẹ̀DÀ Ọ̀RỌ̀ - DR. OLÚWATÓSÌN ÀKÀNDÉ

Ìríran àti ìgbọ́ràn jẹ́ ohun tí àwọn tó ní autism ń ní ìrírí rẹ̀ lọ́nà tó yàtọ̀, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ní autism ń ní ìmọ̀lára lọ́nà tó yàtọ̀. Níní ìmọ̀lára tó ga pàápàá nípa ìríran àti ìgbọ́ràn wọ́pọ̀ láàrin àwọn tó ní autism, èyí tí ó túmọ̀ sí pé ìríran, ìgbọ́ràn, àti ìfọwọ́kàn tó dàbí ohun tó ṣe déédéé tàbí dùn mọ́ àwọn ẹlòmíràn le fa ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí ìnilára fún wọn. Níní òye àwọn ìyàtọ̀ yìí le ran àwọn ẹbí, olùkọ́, àti ọ̀rẹ́ wọn lọ́wọ́ láti ṣẹ̀dá àyíká tó rọrùn fún wọn.

Ó le má rọrùn fún àwọn mìíràn tó ní autism láti ríran. Ó le nira fún àwọn mìíràn láti wo iná tó mọ́lẹ̀ jù, àwọ̀ tó bá ti tàn jù tàbí kí nǹkan tí wọ́n ń wò dédé yí padà, èyí le fa kí ohun tí ó wà nínú ọpọlọ wọn pàpọ̀jù. Bákan náà, àwọn mìíràn le fẹ́ràn àwọn àwòrán kan kí wọ́n sì tẹjú mọ̀ fún ìgbà pípẹ́. Ìmọ̀lára yìí le jẹ́ yàrá tó kún fún èrò, tó ní oríṣiríṣi àwọ̀, nígbàtí ibi tó rọrùn, tí wọ́n tò dáadáa tó sì kún fún ààbò fi wọ́n lára balẹ̀. Ṣíṣàtúnṣe iná, dídín ìgbòkègbodò kù níwájú wọn, tàbí fífi ààyè sílẹ̀ fún wọn láti rẹjú le mú ìyàtọ̀ tó pọ̀ bá ìrọ̀rùn wọn.

Ohùn gbígbọ́ tún jẹ́ ìrírí mìíràn tó jinlẹ̀ fún àwọn tó ní autism. Àwọn kan le ní ìmọ̀lára tó ga sí ohùn gbígbọ́, èyí yóò jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ohùn àwọn nǹkan tí kò pariwo bíi fáànù, àwọn tó ń sọ̀rọ̀ wújẹ́wújẹ́ àbí ìró ẹsẹ̀. Àwọn ìró ojoojúmọ́ yìí le dàbí ariwo kí ó sì fa ìdààmú tó le yọrí sí ìnira, àníyàn àbí sísálọ sí ibi tí kò sí ariwo. Ariwo òjijì bíi ìtanijí tàbí ariwo ọkọ̀ pàjáwìrì le fa wàhálà. Bákan náà, àwọn ohùn kan le dùn mọ́ àwọn mìíràn, bíi ohùn aago tó ń ṣiṣẹ́ lára ògiri tàbí orin aládùn kan tí ń kọ àkọtúnkọ.

Dídá àwọn ìmọ̀lára ìríran àti ohùn yìí mọ̀ yóò fààyè gba fífi-ara-ẹnì-ṣírò àti ìgbárùkù tì. Fún àpẹẹrẹ, dídín ariwo kù, pípèsè ohun tó le dín ariwo kù nínú etí, yínyín iná tó bá mọ́lẹ̀ jù sílẹ̀, àbí ṣíṣàgbékalẹ̀ ibi tí kò sí ariwo tí ó lè dín ríru ẹrù tó pọ̀ sí ọpọlọ kù tí yóò sì mú ìrọ̀rùn wọn gbèrú síi. Nípa bíbọ̀wọ̀ fún àti ṣíṣe àtúnṣe sí àwọn ìmọ̀lára yìí, à ń ṣẹ̀dá àwùjọ tí àwọn tó ní autism yóò ti ní ìmọ̀lára ààbò àti àtìlẹ́yìn, èyí tí yóò fún wọn ní àǹfààní láti darapọ̀ mọ́ àwùjọ kí wọ́n sì le kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́nà tí yóò gbà rọ̀ wọ́n lọ́rùn. Fífi ààyè gbà wọ́n àti níní òye ìríran àti ìgbọ́ràn wọn, kò kàn ní bọ̀wọ̀ fún ìrírí ẹnì kọ̀ọ̀kan nìkan, yóò tún ṣílẹ̀kùn ìbáṣepọ̀ tí ó dán mọ́rán láàrin wọn.

“Bákan náà, àwọn mìíràn le fẹ́ràn àwọn àwòrán kan kí wọ́n sì tẹjú mọ̀ fún ìgbà pípẹ́. Ìmọ̀lára yìí le jẹ́ yàrá tó kún fún èrò, tó ní oríṣiríṣi àwọ̀, nígbàtí ibi tó rọrùn, tí wọ́n tò dáadáa tó sì kún fún ààbò fi wọ́n lára balẹ̀.”

Dr. Oluwatosin Akande

Founder / CEO Bethel Xafe Autism Foundation